Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

Isaiah 30:20 in English

Isaiah 30:20 · Berean Standard Bible

The Lord will give you the bread of adversity and the water of affliction, but your Teacher will no longer hide Himself—with your own eyes you will see Him.

Context

18Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! 19Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. 20Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. 21Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.” 22Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.