Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”

Isaiah 30:11 in English

Isaiah 30:11 · Berean Standard Bible

Get out of the way; turn off the road. Rid us of the Holy One of Israel!”

Context

9Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni Olúwa. 10Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. 11Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!” 12Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbára lé ìnilára kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn, 13ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.