Isaiah 30:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
Isaiah 30:13 in English
Isaiah 30:13 · Berean Standard Bible
this iniquity of yours is like a breach about to fail, a bulge in a high wall, whose collapse will come suddenly— in an instant!
Context
11Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,
ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí
ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá
pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!” 12Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí:
“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,
ẹ gbára lé ìnilára
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn, 13ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ
gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì
tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan. 14Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì
tí a fọ́ pátápátá
àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,
fún mímú èédú kúrò nínú ààrò
tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.” 15Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:
“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.