Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.

Isaiah 26:19 in English

Isaiah 26:19 · Berean Standard Bible

Your dead will live; their bodies will rise. Awake and sing, you who dwell in the dust! For your dew is like the dew of the morning, and the earth will bring forth her dead.

Context

17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa. 18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé. 19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ. 20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá. 21Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀; kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.