Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

Isaiah 26:18 in English

Isaiah 26:18 · Berean Standard Bible

We were with child; we writhed in pain; but we gave birth to wind. We have given no salvation to the earth, nor brought any life into the world.

Context

16Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn; nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn, wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. 17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa. 18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé. 19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ. 20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.