Isaiah 26:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa.
Isaiah 26:17 in English
Isaiah 26:17 · Berean Standard Bible
As a woman with child about to give birth writhes and cries out in pain, so were we in Your presence, O LORD.
Context
15Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;
ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.
Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;
ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn. 16Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn;
nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn,
wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. 17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ
tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa. 18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora,
ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.
Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;
àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé. 19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè
ara wọn yóò dìde.
Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,
dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.
Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,
ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.