Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn; nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn, wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

Isaiah 26:16 in English

Isaiah 26:16 · Berean Standard Bible

O LORD, they sought You in their distress; when You disciplined them, they poured out a quiet prayer.

Context

14Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá. 15Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa; ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i. Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ; ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn. 16Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn; nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn, wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. 17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa. 18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.