Isaiah 26:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀; kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.
Isaiah 26:21 in English
Isaiah 26:21 · Berean Standard Bible
For behold, the LORD is coming out of His dwelling to punish the inhabitants of the earth for their iniquity. The earth will reveal her bloodshed and will no longer conceal her slain.
Context
19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè
ara wọn yóò dìde.
Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,
dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.
Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,
ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ. 20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ
kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín,
ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀
títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá. 21Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀
láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀;
kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.