Isaiah 23:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọjá wá sí Tarṣiṣi; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
Isaiah 23:6 in English
Isaiah 23:6 · Berean Standard Bible
Cross over to Tarshish; wail, O inhabitants of the coastland!
Context
4Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀.
“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.” 5Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
ìròyìn láti Tire. 6Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù. 7Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré. 8Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
ìlú aládé,
àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
ní orílẹ̀ ayé?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.