Isaiah 23:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ló gbèrò èyí sí Tire, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?
Isaiah 23:8 in English
Isaiah 23:8 · Berean Standard Bible
Who planned this against Tyre, the bestower of crowns, whose traders are princes, whose merchants are renowned on the earth?
Context
6Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù. 7Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré. 8Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
ìlú aládé,
àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
ní orílẹ̀ ayé? 9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,
láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba
àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá
ilé ayé sílẹ̀. 10Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.