Isaiah 23:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tire.
Isaiah 23:5 in English
Isaiah 23:5 · Berean Standard Bible
When the report reaches Egypt, they will writhe in agony over the news of Tyre.
Context
3Láti orí àwọn omi ńlá
ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá;
ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,
òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè. 4Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀.
“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.” 5Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
ìròyìn láti Tire. 6Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù. 7Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.