Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

Isaiah 22:19 in English

Isaiah 22:19 · Berean Standard Bible

I will remove you from office, and you will be ousted from your position.

Context

17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára. 18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ! 19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ. 20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.