Isaiah 22:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.
Isaiah 22:20 in English
Isaiah 22:20 · Berean Standard Bible
On that day I will summon My servant, Eliakim son of Hilkiah.
Context
18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ! 19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,
a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ. 20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 22Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.