Isaiah 2:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjì wọ́n.
Isaiah 2:9 in English
Isaiah 2:9 · Berean Standard Bible
So mankind is brought low, and man is humbled— do not forgive them!
Context
7Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. 8Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe. 9Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
má ṣe dáríjì wọ́n. 10Wọ inú àpáta lọ,
fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
àti ògo ọláńlá rẹ̀! 11Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.