Isaiah 2:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
Isaiah 2:11 in English
Isaiah 2:11 · Berean Standard Bible
The proud look of man will be humbled, and the loftiness of men brought low; the LORD alone will be exalted in that day.
Context
9Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
má ṣe dáríjì wọ́n. 10Wọ inú àpáta lọ,
fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
àti ògo ọláńlá rẹ̀! 11Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà. 12Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́
fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga
nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀), 13nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó
àti gbogbo óákù Baṣani,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.