Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.

Isaiah 2:7 in English

Isaiah 2:7 · Berean Standard Bible

Their land is full of silver and gold, with no limit to their treasures; their land is full of horses, with no limit to their chariots.

Context

5Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu, ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa. 6Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jakọbu. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini, wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà. 7Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. 8Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe. 9Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjì wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.