Isaiah 2:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu, ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.
Isaiah 2:5 in English
Isaiah 2:5 · Berean Standard Bible
Come, O house of Jacob, let us walk in the light of the LORD.
Context
3Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu. 4Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. 5Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa. 6Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
ìwọ ilé Jakọbu.
Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà. 7Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.