Isaiah 2:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
Isaiah 2:8 in English
Isaiah 2:8 · Berean Standard Bible
Their land is full of idols; they bow down to the work of their hands, to what their fingers have made.
Context
6Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
ìwọ ilé Jakọbu.
Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà. 7Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. 8Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe. 9Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
má ṣe dáríjì wọ́n. 10Wọ inú àpáta lọ,
fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
àti ògo ọláńlá rẹ̀!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.