Isaiah 17:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
Isaiah 17:11 in English
Isaiah 17:11 · Berean Standard Bible
though on the day you plant you make them grow, and on that morning you help your seed sprout— yet the harvest will vanish on the day of disease and incurable pain.
Context
9Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro. 10Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀. 11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn. 12Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá! 13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.