Isaiah 17:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
Isaiah 17:10 in English
Isaiah 17:10 · Berean Standard Bible
For you have forgotten the God of your salvation and failed to remember the Rock of your refuge. Therefore, though you cultivate delightful plots and set out cuttings from exotic vines—
Context
8Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe. 9Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro. 10Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀. 11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn. 12Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.