Isaiah 17:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun! Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
Isaiah 17:12 in English
Isaiah 17:12 · Berean Standard Bible
Alas, the tumult of many peoples; they rage like the roaring seas and clamoring nations; they rumble like the crashing of mighty waters.
Context
10Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀. 11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn. 12Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá! 13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle. 14Ní aginjù, ìpayà òjijì!
Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.