Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

Isaiah 10:8 in English

Isaiah 10:8 · Berean Standard Bible

“Are not all my commanders kings?” he says.

Context

6Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run, mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó. 7Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. 8‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí. 9‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi? Hamati kò ha dàbí i Arpadi, àti Samaria bí i Damasku? 10Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.