Isaiah 10:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
Isaiah 10:7 in English
Isaiah 10:7 · Berean Standard Bible
But this is not his intention; this is not his plan. For it is in his heart to destroy and cut off many nations.
Context
5“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà! 6Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run,
mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó. 7Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
èrò rẹ̀ ni láti parun,
láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. 8‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí. 9‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
àti Samaria bí i Damasku?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.