Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

Hosea 9:16 in English

Hosea 9:16 · Berean Standard Bible

Ephraim is struck down; their root is withered; they cannot bear fruit. Even if they bear children, I will slay the darlings of their wombs.

Context

14Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ. 15“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali, Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi, Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn. 16Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.” 17Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.