Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ.

Hosea 9:14 in English

Hosea 9:14 · Berean Standard Bible

Give them, O LORD— what will You give? Give them wombs that miscarry and breasts that dry up!

Context

12Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn. Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn! 13Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.” 14Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ. 15“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali, Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi, Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn. 16Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.