Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn. Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!

Hosea 9:12 in English

Hosea 9:12 · Berean Standard Bible

Even if they raise their children, I will bereave them of each one. Yes, woe be to them when I turn away from them!

Context

10“Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù. Mo rí àwọn baba yín, bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ, wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni, ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ. 12Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn. Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn! 13Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.” 14Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.