Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali, Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi, Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.

Hosea 9:15 in English

Hosea 9:15 · Berean Standard Bible

All their evil appears at Gilgal, for there I hated them. I will drive them from My house for the wickedness of their deeds. I will no longer love them; all their leaders are rebellious.

Context

13Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.” 14Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ. 15“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali, Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi, Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn. 16Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.” 17Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.