Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.

Hosea 7:5 in English

Hosea 7:5 · Berean Standard Bible

The princes are inflamed with wine on the day of our king; so he joins hands with those who mock him.

Context

3“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn. 4Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí a dáwọ́ kíkoná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú. 5Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́. 6Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀. 7Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.