Hosea 7:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn.
Hosea 7:3 in English
Hosea 7:3 · Berean Standard Bible
They delight the king with their evil, and the princes with their lies.
Context
1nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá.
Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn
ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta.
Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn,
àwọn olè ń fọ́ ilé;
àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà; 2ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé
mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn.
Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá;
wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo. 3“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,
àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn. 4Alágbèrè ni gbogbo wọn
wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà
tí a dáwọ́ kíkoná dúró,
lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú. 5Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa
wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná
ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.