Hosea 5:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Fọn fèrè ní Gibeah, kí ẹ sì fun ìpè ní Rama. Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni; máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
Hosea 5:8 in English
Hosea 5:8 · Berean Standard Bible
Blow the ram’s horn in Gibeah, the trumpet in Ramah; raise the battle cry in Beth-aven:* Lead on, O Benjamin!
Context
6Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn. 7Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn. 8“Fọn fèrè ní Gibeah,
kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni;
máa wárìrì, ìwọ Benjamini. 9Efraimu yóò di ahoro
ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli,
Mo sọ ohun tí ó dájú. 10Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
wọn lórí bí ìkún omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.