Hosea 5:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi.
Hosea 5:10 in English
Hosea 5:10 · Berean Standard Bible
The princes of Judah are like those who move boundary stones;* I will pour out My fury upon them like water.
Context
8“Fọn fèrè ní Gibeah,
kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni;
máa wárìrì, ìwọ Benjamini. 9Efraimu yóò di ahoro
ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli,
Mo sọ ohun tí ó dájú. 10Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
wọn lórí bí ìkún omi. 11A ni Efraimu lára,
a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́,
nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà. 12Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu,
Mo sì dàbí ìdin ara Juda.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.