Hosea 12:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
Hosea 12:4 in English
Hosea 12:4 · Berean Standard Bible
Yes, he struggled with the angel * and prevailed; he wept and sought His favor; he found Him at Bethel and spoke with Him there *—
Context
2Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò,
yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀. 3Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,
àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run 4Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀,
o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀.
Ó bá Olúwa ní Beteli,
Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, 5àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun;
Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀. 6Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.