Hosea 12:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
Hosea 12:6 in English
Hosea 12:6 · Berean Standard Bible
But you must return to your God, maintaining love and justice, and always waiting on your God.
Context
4Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀,
o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀.
Ó bá Olúwa ní Beteli,
Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, 5àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun;
Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀. 6Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. 7Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké
o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. 8Efraimu gbéraga,
“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,
pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé
tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.