Hosea 12:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
Hosea 12:8 in English
Hosea 12:8 · Berean Standard Bible
And Ephraim boasts: “How rich I have become! I have found wealth for myself. In all my labors, they can find in me no iniquity that is sinful.”
Context
6Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. 7Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké
o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. 8Efraimu gbéraga,
“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,
pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé
tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.” 9“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;
ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti;
èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́
bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì. 10Mo sọ fún àwọn wòlíì,
mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n
mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.