Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì.

Hosea 12:9 in English

Hosea 12:9 · Berean Standard Bible

But I am the LORD your God ever since the land of Egypt. I will again make you dwell in tents, as in the days of the appointed feast.

Context

7Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. 8Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.” 9“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì. 10Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.” 11Gileadi ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.