Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

Hosea 12:3 in English

Hosea 12:3 · Berean Standard Bible

In the womb he grasped his brother’s heel, and in his vigor he wrestled with God.

Context

1Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́; o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́. O sì ń gbèrú nínú irọ́ o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti. 2Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò, yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀. 3Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run 4Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, 5àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.