Hosea 11:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.
Hosea 11:7 in English
Hosea 11:7 · Berean Standard Bible
My people are bent on turning from Me. Though they call to the Most High, He will by no means exalt them.
Context
5“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí.
Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí
nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà? 6Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn
yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́
yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn. 7Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi
bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,
kò ní gbé wọn ga rárá. 8“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?
Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Seboimu?
Ọkàn mi yípadà nínú mi
àánú mi sì ru sókè. 9Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,
tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.
Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn.
Ẹni mímọ́ láàrín yín,
Èmi kò ní í wá nínú ìbínú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.