Hosea 11:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí. Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
Hosea 11:5 in English
Hosea 11:5 · Berean Standard Bible
Will they not return to the land of Egypt and be ruled by Assyria because they refused to repent?
Context
3Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn
mo di wọ́n mú ní apá,
ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀
pé mo ti mú wọn láradá. 4Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n
àti ìdè ìfẹ́.
Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn,
Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ. 5“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí.
Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí
nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà? 6Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn
yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́
yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn. 7Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi
bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,
kò ní gbé wọn ga rárá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.