Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá.

Hosea 11:3 in English

Hosea 11:3 · Berean Standard Bible

It was I who taught Ephraim * to walk, taking them in My arms, but they never realized that it was I who healed them.

Context

1“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá. 2Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín. 3Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá. 4Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn, Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ. 5“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí. Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.