Hosea 10:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín,
Hosea 10:13 in English
Hosea 10:13 · Berean Standard Bible
You have plowed wickedness and reaped injustice; you have eaten the fruit of lies. Because you have trusted in your own way and in the multitude of your mighty men,
Context
11Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́,
to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà;
lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni
èmi ó dí ẹrù wúwo lé.
Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin
Juda yóò tú ilẹ̀,
Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀. 12Ẹ gbin òdòdó fún ara yín,
kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin.
Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro,
nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,
títí tí yóò fi dé,
tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí. 13Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi,
ẹ ti jẹ èso èké
nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín
àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín, 14ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín
kí gbogbo odi agbára yín ba le parun.
Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun,
nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. 15Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli,
nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù.
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,
a o pa ọba Israẹli run pátápátá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.