Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

Hosea 10:12 in English

Hosea 10:12 · Berean Standard Bible

Sow for yourselves righteousness and reap the fruit of loving devotion; break up your unplowed ground. For it is time to seek the LORD until He comes and sends righteousness upon you like rain.

Context

10Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn, láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà; lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹrù wúwo lé. Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin Juda yóò tú ilẹ̀, Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀. 12Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí. 13Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín, 14ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.