Heberu 3:15
Hebrews 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí a ń wí pé, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má sé ọkàn yin le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”
Hebrews 3:15 in English
Hebrews 3:15 · Berean Standard Bible
As it has been said: “Today, if you hear His voice, do not harden your hearts, as you did in the rebellion.”*
Context
13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin. 15Nígbà tí a ń wí pé,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.” 16Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.