Heberu 3:13
Hebrews 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.
Hebrews 3:13 in English
Hebrews 3:13 · Berean Standard Bible
But exhort one another daily, as long as it is called today, so that none of you may be hardened by sin’s deceitfulness.
Context
11Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
‘Wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” 12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin. 15Nígbà tí a ń wí pé,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.