Heberu 3:14
Hebrews 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin.
Hebrews 3:14 in English
Hebrews 3:14 · Berean Standard Bible
We have come to share in Christ if we hold firmly to the end the assurance we had at first.
Context
12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin. 15Nígbà tí a ń wí pé,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.” 16Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.