Native Bible

Hebrews 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.

Hebrews 3:12 in English

Hebrews 3:12 · Berean Standard Bible

See to it, brothers, that none of you has a wicked heart of unbelief that turns away from the living God.

Context

10Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn; wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’ 11Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” 12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.