Native Bible

Habakkuk 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

Habakkuk 2:3 in English

Habakkuk 2:3 · Berean Standard Bible

For the vision awaits an appointed time; it testifies of the end and does not lie. Though it lingers, wait for it, since it will surely come and will not delay.*

Context

1Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye, èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre, èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí. 2Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé, “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré. 3Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.” 4“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga, ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. 5Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn, agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú, ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.