Native Bible

Habakkuk 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye, èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre, èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

Habakkuk 2:1 in English

Habakkuk 2:1 · Berean Standard Bible

I will stand at my guard post and station myself on the ramparts. I will watch to see what He will say to me, and how I should answer when corrected.

Context

1Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye, èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre, èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí. 2Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé, “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré. 3Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.