Habakuku 2:16
Habakkuk 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn, ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
Habakkuk 2:16 in English
Habakkuk 2:16 · Berean Standard Bible
You will be filled with shame instead of glory. You too must drink and expose your uncircumcision!* The cup in the LORD’s right hand will come around to you, and utter disgrace will cover your glory.
Context
14Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun. 15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.” 16Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,
ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ. 17Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀.
Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 18“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
ère dídá ti ń kọ ni èké?
Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá;
ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.