Native Bible

Habakkuk 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

Habakkuk 2:17 in English

Habakkuk 2:17 · Berean Standard Bible

For your violence against Lebanon will overwhelm you, and the destruction of animals will terrify you, because of your bloodshed against men and your violence against the land, the city, and all their dwellers.

Context

15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.” 16Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn, ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ. 17Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 18“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá ti ń kọ ni èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn. 19Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.