Native Bible

Habakkuk 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”

Habakkuk 2:15 in English

Habakkuk 2:15 · Berean Standard Bible

Woe to him who gives drink to his neighbors, pouring it from the wineskin until they are drunk, in order to gaze at their nakedness!

Context

13Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán? 14Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa, bí omi ti bo Òkun. 15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.” 16Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn, ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ. 17Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.